Ẹkún Jeremiah 5:13
Lamentations 5:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wa ru òkúta; àwọn ọmọkùnrin sì ń ṣàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi.
Lamentations 5:13 in English
Lamentations 5:13 · Berean Standard Bible
Young men toil at millstones; boys stagger under loads of wood.
Context
11Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lòpọ̀ ní Sioni,
àti àwọn wúńdíá ti o wa ní ìlú Juda. 12Àwọn ọmọ ọbakùnrin ti di síso sókè ní ọwọ́ wọn;
kò sí ìbọ̀wọ̀ fún àgbàgbà mọ́. 13Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wa ru òkúta;
àwọn ọmọkùnrin sì ń ṣàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi. 14Àwọn àgbàgbà ti lọ kúrò ní ẹnu-bodè ìlú;
àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì dákẹ́ orin wọn. 15Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa;
ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.