Native Bible

Lamentations 4:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Síwájú sí i, ojú wa kùnà fún wíwo ìrànlọ́wọ́ asán; láti orí ìṣọ́ wa ni à ń wò fún orílẹ̀-èdè tí kò le gbà wá là.

Lamentations 4:17 in English

Lamentations 4:17 · Berean Standard Bible

All the while our eyes were failing as we looked in vain for help. We watched from our towers for a nation that could not save us.

Context

15“Lọ kúrò! Ẹ̀yin di aláìmọ́!” ni àwọn ènìyàn ń kígbe sí wọn. “Ẹ lọ! Ẹ lọ! Ẹ má ṣe fọwọ́ kàn wá!” Àwọn ènìyàn láàrín orílẹ̀-èdè wí pé, “Wọn kì yóò tẹ̀dó síbí mọ́.” 16Olúwa ti tú wọn ká fúnra rẹ̀; kò sí bojútó wọn mọ́. Kò sí ọ̀wọ̀ fún olórí àlùfáà mọ́, àti àánú fún àwọn àgbàgbà. 17Síwájú sí i, ojú wa kùnà fún wíwo ìrànlọ́wọ́ asán; láti orí ìṣọ́ wa ni à ń wò fún orílẹ̀-èdè tí kò le gbà wá là. 18Wọ́n ń ṣọ́ wa kiri, àwa kò sì le rìn ní òpópó wa mọ́. Òpin wa ti súnmọ́, ọjọ́ wa sì níye nítorí òpin wa ti dé. 19Àwọn tí ń lé wa yára ju idì ojú ọ̀run lọ; wọ́n lé wa ní gbogbo orí òkè wọ́n sì gẹ̀gùn dè wá ní aginjù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.