Ẹkún Jeremiah 4:16
Lamentations 4:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa ti tú wọn ká fúnra rẹ̀; kò sí bojútó wọn mọ́. Kò sí ọ̀wọ̀ fún olórí àlùfáà mọ́, àti àánú fún àwọn àgbàgbà.
Lamentations 4:16 in English
Lamentations 4:16 · Berean Standard Bible
The presence of the LORD has scattered them; He regards them no more. The priests are shown no honor; the elders find no favor.
Context
14Nísinsin yìí wọ́n ń rìn kiri ní òpópó
bí ọkùnrin tí ó fọ́jú.
Ẹ̀jẹ̀ ara wọn sọ wọ́n di àbàwọ́n
tí kò sẹ́ni tó láyà láti fọwọ́ kan aṣọ wọn. 15“Lọ kúrò! Ẹ̀yin di aláìmọ́!” ni àwọn ènìyàn ń kígbe sí wọn.
“Ẹ lọ! Ẹ lọ! Ẹ má ṣe fọwọ́ kàn wá!”
Àwọn ènìyàn láàrín orílẹ̀-èdè wí pé,
“Wọn kì yóò tẹ̀dó síbí mọ́.” 16Olúwa ti tú wọn ká fúnra rẹ̀;
kò sí bojútó wọn mọ́.
Kò sí ọ̀wọ̀ fún olórí àlùfáà mọ́,
àti àánú fún àwọn àgbàgbà. 17Síwájú sí i, ojú wa kùnà
fún wíwo ìrànlọ́wọ́ asán;
láti orí ìṣọ́ wa ni à ń wò
fún orílẹ̀-èdè tí kò le gbà wá là. 18Wọ́n ń ṣọ́ wa kiri,
àwa kò sì le rìn ní òpópó wa mọ́.
Òpin wa ti súnmọ́, ọjọ́ wa sì níye
nítorí òpin wa ti dé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.