Ẹkún Jeremiah 2:21
Lamentations 2:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ọmọdé àti àgbà ń sùn papọ̀ sínú eruku àwọn òpópó; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi ti ṣègbé nípa idà. Ìwọ pa wọ́n run ní ọjọ́ ìbínú rẹ, Ìwọ pa wọ́n láìní àánú.
Lamentations 2:21 in English
Lamentations 2:21 · Berean Standard Bible
Both young and old lie together in the dust of the streets. My young men and maidens have fallen by the sword. You have slain them in the day of Your anger; You have slaughtered them without compassion.
Context
19Dìde, kígbe sókè ní àṣálẹ́,
bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀
tú ọkàn rẹ̀ jáde bí omi
níwájú Olúwa.
Gbé ọwọ́ yín sókè sí i
nítorí ẹ̀mí àwọn èwe rẹ̀
tí ó ń kú lọ nítorí ebi
ní gbogbo oríta òpópó. 20“Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó.
Ta ni ìwọ ti fìyà jẹ bí èyí.
Ǹjẹ́ àwọn obìnrin yóò ha jẹ ọmọ wọn,
àwọn ọmọ tí wọn ń ṣe ìtọ́jú fún?
Ǹjẹ́ kí a pa olórí àlùfáà àti àwọn wòlíì
ní ibi mímọ́ Olúwa? 21“Ọmọdé àti àgbà ń sùn papọ̀
sínú eruku àwọn òpópó;
àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi
ti ṣègbé nípa idà.
Ìwọ pa wọ́n run ní ọjọ́ ìbínú rẹ,
Ìwọ pa wọ́n láìní àánú. 22“Bí ó ti ṣe ní ọjọ́ àsè,
bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi ẹ̀rù sí ẹ̀gbẹ́ mi.
Ní ọjọ́ ìbínú Olúwa
kò sí ẹni tí ó sálà tí ó sì yè;
àwọn tí mo ti tọ́jú tí mo sì fẹ́ràn,
ni ọ̀tá mi parun.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.