Joṣua 9:8
Joshua 9:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ìránṣẹ́ rẹ ní àwa í ṣe.” Wọ́n sọ fún Joṣua. Ṣùgbọ́n Joṣua béèrè, “Ta ni yín àti pé níbo ni ẹ̀yin ti wá?”
Joshua 9:8 in English
Joshua 9:8 · Berean Standard Bible
“We are your servants,” they said to Joshua. Then Joshua asked them, “Who are you and where have you come from?”
Context
6Wọ́n sì tọ Joṣua lọ ní ibùdó ní Gilgali, wọ́n sì sọ fún òun àti àwọn ọkùnrin Israẹli pé, “Ìlú òkèrè ní àwọn ti wá, ẹ ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wa.” 7Àwọn ọkùnrin Israẹli sọ fún àwọn ará Hifi pé, “Ṣùgbọ́n bóyá tòsí wa ni ẹ ń gbé. Báwo ni a ó ṣe lè ṣe àdéhùn pẹ̀lú yín?” 8“Ìránṣẹ́ rẹ ní àwa í ṣe.” Wọ́n sọ fún Joṣua.
Ṣùgbọ́n Joṣua béèrè, “Ta ni yín àti pé níbo ni ẹ̀yin ti wá?” 9Wọ́n sì dáhùn pé, “Ní ilẹ̀ òkèèrè ní àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wá, nítorí orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí tí àwa ti gbọ́ òkìkí rẹ àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe ní Ejibiti, 10àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe sí ọba àwọn Amori méjèèje tí ń bẹ ní òkè Jordani, sí Sihoni ọba Heṣboni, àti Ogu ọba Baṣani, tí wọ́n jẹ ọba ní Aṣtarotu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.