Joṣua 9:6
Joshua 9:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì tọ Joṣua lọ ní ibùdó ní Gilgali, wọ́n sì sọ fún òun àti àwọn ọkùnrin Israẹli pé, “Ìlú òkèrè ní àwọn ti wá, ẹ ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wa.”
Joshua 9:6 in English
Joshua 9:6 · Berean Standard Bible
They went to Joshua in the camp at Gilgal and said to him and the men of Israel, “We have come from a distant land; please make a treaty * with us.”
Context
4wọ́n dá ọgbọ́n ẹ̀tàn. Wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí aṣojú tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn kún fún ẹrù tí a fi àwọn àpò tó ti gbó dì, àti àwọn awọ ọtí wáìnì tó ti gbó tí a tún rán. 5Àwọn ọkùnrin náà sì wọ bàtà àti aṣọ tí ó ti gbó. Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n pèsè fún ara wọn sì bu. 6Wọ́n sì tọ Joṣua lọ ní ibùdó ní Gilgali, wọ́n sì sọ fún òun àti àwọn ọkùnrin Israẹli pé, “Ìlú òkèrè ní àwọn ti wá, ẹ ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wa.” 7Àwọn ọkùnrin Israẹli sọ fún àwọn ará Hifi pé, “Ṣùgbọ́n bóyá tòsí wa ni ẹ ń gbé. Báwo ni a ó ṣe lè ṣe àdéhùn pẹ̀lú yín?” 8“Ìránṣẹ́ rẹ ní àwa í ṣe.” Wọ́n sọ fún Joṣua.
Ṣùgbọ́n Joṣua béèrè, “Ta ni yín àti pé níbo ni ẹ̀yin ti wá?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.