Joṣua 22:29
Joshua 22:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Kí Ọlọ́run má jẹ́ kí àwa kí ó ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa, kí àwa sì yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ ní òní nípa mímọ pẹpẹ ẹbọ sísun, ọrẹ oúnjẹ jíjẹ àti ẹbọ lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa tí ó dúró níwájú àgọ́ rẹ̀.”
Joshua 22:29 in English
Joshua 22:29 · Berean Standard Bible
Far be it from us to rebel against the LORD and turn away from Him today by building an altar for burnt offerings, grain offerings, or sacrifices, other than the altar of the LORD our God, which stands before His tabernacle.”
Context
27Ní ọ̀nà mìíràn, yóò jẹ́ ẹ̀rí kan láàrín àwa àti ẹ̀yin àti àwọn ìran tí ń bọ̀, pé àwa yóò jọ́sìn fún Olúwa ní ibi mímọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun wa, ẹbọ àti ọrẹ àlàáfíà. Nígbà náà ni ẹ̀yìn ọ̀la, àwọn ọmọ yín kò ní lè sọ fún tiwa pé, ‘Ẹ kò ní ìpín nínú ti Olúwa.’ 28“Àwa sì wí pé, ‘Tí wọ́n bá tilẹ̀ sọ èyí fún wa, tàbí sí àwọn ọmọ wa, a ó dáhùn pé, “Ẹ wo àpẹẹrẹ pẹpẹ Olúwa, èyí tí àwọn baba wa mọ, kì í ṣe fún ẹbọ sísun àti ẹbọ ṣùgbọ́n fún ẹ̀rí láàrín àwa àti ẹ̀yin.” ’ 29“Kí Ọlọ́run má jẹ́ kí àwa kí ó ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa, kí àwa sì yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ ní òní nípa mímọ pẹpẹ ẹbọ sísun, ọrẹ oúnjẹ jíjẹ àti ẹbọ lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa tí ó dúró níwájú àgọ́ rẹ̀.” 30Nígbà tí Finehasi àlùfáà àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn, àwọn olórí ìdílé Israẹli gbọ́ ohun tí Reubeni, Gadi àti Manase ti sọ, ó dùn mọ́ wọn. 31Finehasi ọmọ Eleasari, àlùfáà wí fún Reubeni, Gadi àti Manase pé, “Ní òní ni àwa mọ̀ pé Olúwa wà pẹ̀lú wa, nítorí tí ẹ̀yin kò hùwà àìṣòótọ́ sí Olúwa ní orí ọ̀rọ̀ yí nísinsin yìí, ẹ̀yin ti yọ àwọn ará Israẹli kúrò ní ọwọ́ Olúwa”.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.