Joṣua 22:31
Joshua 22:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Finehasi ọmọ Eleasari, àlùfáà wí fún Reubeni, Gadi àti Manase pé, “Ní òní ni àwa mọ̀ pé Olúwa wà pẹ̀lú wa, nítorí tí ẹ̀yin kò hùwà àìṣòótọ́ sí Olúwa ní orí ọ̀rọ̀ yí nísinsin yìí, ẹ̀yin ti yọ àwọn ará Israẹli kúrò ní ọwọ́ Olúwa”.
Joshua 22:31 in English
Joshua 22:31 · Berean Standard Bible
Phinehas son of Eleazar the priest said to the descendants of Reuben, Gad, and Manasseh, “Today we know that the LORD is among us, because you have not committed this breach of faith against Him. Consequently, you have delivered the Israelites from the hand of the LORD.”
Context
29“Kí Ọlọ́run má jẹ́ kí àwa kí ó ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa, kí àwa sì yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ ní òní nípa mímọ pẹpẹ ẹbọ sísun, ọrẹ oúnjẹ jíjẹ àti ẹbọ lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa tí ó dúró níwájú àgọ́ rẹ̀.” 30Nígbà tí Finehasi àlùfáà àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn, àwọn olórí ìdílé Israẹli gbọ́ ohun tí Reubeni, Gadi àti Manase ti sọ, ó dùn mọ́ wọn. 31Finehasi ọmọ Eleasari, àlùfáà wí fún Reubeni, Gadi àti Manase pé, “Ní òní ni àwa mọ̀ pé Olúwa wà pẹ̀lú wa, nítorí tí ẹ̀yin kò hùwà àìṣòótọ́ sí Olúwa ní orí ọ̀rọ̀ yí nísinsin yìí, ẹ̀yin ti yọ àwọn ará Israẹli kúrò ní ọwọ́ Olúwa”. 32Nígbà náà ni Finehasi ọmọ Eleasari àlùfáà àti àwọn olórí padà sí Kenaani láti ibi ìpàdé wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Reubeni àti ẹ̀yà Gadi ní Gileadi, wọ́n sì mú ìròyìn tọ àwọn ọmọ Israẹli lọ. 33Inú wọn sì dùn láti gbọ́ ìròyìn náà, wọ́n sì yin Ọlọ́run. Wọn kò sì sọ̀rọ̀ mọ́ nípa lílọ bá wọn jagun láti run ilẹ̀ tí àwọn ẹ̀yà Reubeni àti ẹ̀yà Gadi ń gbé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.