Native Bible

Joshua 22:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Àwa sì wí pé, ‘Tí wọ́n bá tilẹ̀ sọ èyí fún wa, tàbí sí àwọn ọmọ wa, a ó dáhùn pé, “Ẹ wo àpẹẹrẹ pẹpẹ Olúwa, èyí tí àwọn baba wa mọ, kì í ṣe fún ẹbọ sísun àti ẹbọ ṣùgbọ́n fún ẹ̀rí láàrín àwa àti ẹ̀yin.” ’

Joshua 22:28 in English

Joshua 22:28 · Berean Standard Bible

Therefore we said, ‘If they ever say this to us or to our descendants, we will answer: Look at the replica of the altar of the LORD that our fathers made, not for burnt offerings or sacrifices, but as a witness between us and you.’

Context

26“Nítorí èyí ni àwa ṣe wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí àwa múra láti mọ pẹpẹ kan, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún ẹbọ sísun, tàbí fún àwọn ìrúbọ.’ 27Ní ọ̀nà mìíràn, yóò jẹ́ ẹ̀rí kan láàrín àwa àti ẹ̀yin àti àwọn ìran tí ń bọ̀, pé àwa yóò jọ́sìn fún Olúwa ní ibi mímọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ẹbọ sísun wa, ẹbọ àti ọrẹ àlàáfíà. Nígbà náà ni ẹ̀yìn ọ̀la, àwọn ọmọ yín kò ní lè sọ fún tiwa pé, ‘Ẹ kò ní ìpín nínú ti Olúwa.’ 28“Àwa sì wí pé, ‘Tí wọ́n bá tilẹ̀ sọ èyí fún wa, tàbí sí àwọn ọmọ wa, a ó dáhùn pé, “Ẹ wo àpẹẹrẹ pẹpẹ Olúwa, èyí tí àwọn baba wa mọ, kì í ṣe fún ẹbọ sísun àti ẹbọ ṣùgbọ́n fún ẹ̀rí láàrín àwa àti ẹ̀yin.” ’ 29“Kí Ọlọ́run má jẹ́ kí àwa kí ó ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa, kí àwa sì yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ ní òní nípa mímọ pẹpẹ ẹbọ sísun, ọrẹ oúnjẹ jíjẹ àti ẹbọ lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa tí ó dúró níwájú àgọ́ rẹ̀.” 30Nígbà tí Finehasi àlùfáà àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn, àwọn olórí ìdílé Israẹli gbọ́ ohun tí Reubeni, Gadi àti Manase ti sọ, ó dùn mọ́ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.