Joṣua 21:20
Joshua 21:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìyókù ìdílé Kohati tí ó jẹ́ ọmọ Lefi ní a pín ìlú fún láti ara ẹ̀yà Efraimu.
Joshua 21:20 in English
Joshua 21:20 · Berean Standard Bible
The remaining Kohathite clans of the Levites were allotted these cities: From the tribe of Ephraim
Context
18Anatoti àti Almoni, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin. 19Gbogbo ìlú àwọn àlùfáà, ìran Aaroni jẹ́ mẹ́tàlá pẹ̀lú ilẹ̀ pápá wọn. 20Ìyókù ìdílé Kohati tí ó jẹ́ ọmọ Lefi ní a pín ìlú fún láti ara ẹ̀yà Efraimu. 21Ní ilẹ̀ òkè Efraimu wọ́n fún wọn ní:
Ṣekemu (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn) àti Geseri, 22Kibasaimu àti Beti-Horoni, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú mẹ́rin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.