Native Bible

Joshua 2:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí àwọn ayọ́lẹ̀wò náà tó sùn ní alẹ́, ó gòkè tọ̀ wọ́n lọ lókè àjà.

Joshua 2:8 in English

Joshua 2:8 · Berean Standard Bible

Before the spies lay down for the night, Rahab went up on the roof

Context

6(Ṣùgbọ́n ó ti mú wọn gòkè àjà ó sì fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ pòròpòrò ọkà tó tò jọ sí orí àjà.) 7Àwọn ọkùnrin náà jáde lọ láti lépa àwọn ayọ́lẹ̀wò náà ní ọ̀nà tí ó lọ sí ìwọdò Jordani, bí àwọn tí ń lépa wọn sì ti jáde, wọ́n ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè. 8Kí àwọn ayọ́lẹ̀wò náà tó sùn ní alẹ́, ó gòkè tọ̀ wọ́n lọ lókè àjà. 9Ó sì sọ fún wọn, “Èmi mọ̀ pé Olúwa ti fún un yín ní ilẹ̀ yìí àti pé ẹ̀rù u yín ti sọ wá di ojo dé ibi pé ìdí gbogbo àwọn tí ó n gbé ilẹ̀ yìí ti di omi nítorí i yín. 10Àwa ti gbọ́ bí Olúwa ti mú omi Òkun Pupa gbẹ níwájú u yín nígbà tí ẹ̀yin jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, àti ohun tí ẹ̀yin ṣe sí Sihoni àti Ogu, àwọn ọba méjèèjì ti Amori ti ìlà-oòrùn Jordani, tí ẹ̀yin parun pátápátá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.