Joṣua 2:7
Joshua 2:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọkùnrin náà jáde lọ láti lépa àwọn ayọ́lẹ̀wò náà ní ọ̀nà tí ó lọ sí ìwọdò Jordani, bí àwọn tí ń lépa wọn sì ti jáde, wọ́n ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè.
Joshua 2:7 in English
Joshua 2:7 · Berean Standard Bible
So the king’s men set out in pursuit of the spies along the road to the fords of the Jordan, and as soon as they had gone out, the gate was shut.
Context
5Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, nígbà tí ó tó àkókò láti ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè, àwọn ọkùnrin náà sì jáde lọ. Èmi kò sì mọ ọ̀nà tí wọ́n gbà lọ. Ẹ lépa wọn kíákíá. Ẹ̀yin yóò bá wọn.” 6(Ṣùgbọ́n ó ti mú wọn gòkè àjà ó sì fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ pòròpòrò ọkà tó tò jọ sí orí àjà.) 7Àwọn ọkùnrin náà jáde lọ láti lépa àwọn ayọ́lẹ̀wò náà ní ọ̀nà tí ó lọ sí ìwọdò Jordani, bí àwọn tí ń lépa wọn sì ti jáde, wọ́n ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè. 8Kí àwọn ayọ́lẹ̀wò náà tó sùn ní alẹ́, ó gòkè tọ̀ wọ́n lọ lókè àjà. 9Ó sì sọ fún wọn, “Èmi mọ̀ pé Olúwa ti fún un yín ní ilẹ̀ yìí àti pé ẹ̀rù u yín ti sọ wá di ojo dé ibi pé ìdí gbogbo àwọn tí ó n gbé ilẹ̀ yìí ti di omi nítorí i yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.