Joṣua 2:6
Joshua 2:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
(Ṣùgbọ́n ó ti mú wọn gòkè àjà ó sì fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ pòròpòrò ọkà tó tò jọ sí orí àjà.)
Joshua 2:6 in English
Joshua 2:6 · Berean Standard Bible
(But Rahab had taken them up to the roof and hidden them among the stalks of flax that she had laid out there.)
Context
4Ṣùgbọ́n obìnrin náà ti mú àwọn ọkùnrin méjì náà o sì fi wọ́n pamọ́. Ó sì wí pé, “Lóòtítọ́ ní àwọn ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi, ṣùgbọ́n èmi kò mọ ibi tí wọ́n ti wá. 5Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, nígbà tí ó tó àkókò láti ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè, àwọn ọkùnrin náà sì jáde lọ. Èmi kò sì mọ ọ̀nà tí wọ́n gbà lọ. Ẹ lépa wọn kíákíá. Ẹ̀yin yóò bá wọn.” 6(Ṣùgbọ́n ó ti mú wọn gòkè àjà ó sì fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ pòròpòrò ọkà tó tò jọ sí orí àjà.) 7Àwọn ọkùnrin náà jáde lọ láti lépa àwọn ayọ́lẹ̀wò náà ní ọ̀nà tí ó lọ sí ìwọdò Jordani, bí àwọn tí ń lépa wọn sì ti jáde, wọ́n ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè. 8Kí àwọn ayọ́lẹ̀wò náà tó sùn ní alẹ́, ó gòkè tọ̀ wọ́n lọ lókè àjà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.