Joṣua 12:1
Joshua 12:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Israẹli ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, láti odò Arnoni dé òkè Hermoni, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù:
Joshua 12:1 in English
Joshua 12:1 · Berean Standard Bible
Now these are the kings of the land whom the Israelites struck down and whose lands they took beyond the Jordan to the east, from the Arnon Valley to Mount Hermon, including all the Arabah eastward:
Context
1Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Israẹli ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, láti odò Arnoni dé òkè Hermoni, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù: 2Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni.
Ó ṣe àkóso láti Aroeri tí ń bẹ ní etí odò Arnoni, láti ìlú tó wà ní àárín àfonífojì náà dé odò Jabbok, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ammoni. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gileadi. 3Ó sì ṣe àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kinnereti sí ìhà Òkun ti aginjù (ti o túmọ̀ sí Òkun Iyọ̀), sí Beti-Jeṣimoti, àti láti gúúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Pisga.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.