Joṣua 12:2
Joshua 12:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni. Ó ṣe àkóso láti Aroeri tí ń bẹ ní etí odò Arnoni, láti ìlú tó wà ní àárín àfonífojì náà dé odò Jabbok, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ammoni. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gileadi.
Joshua 12:2 in English
Joshua 12:2 · Berean Standard Bible
Sihon king of the Amorites, who lived in Heshbon. He ruled from Aroer on the rim of the Arnon Valley, along the middle of the valley, up to the Jabbok River (the border of the Ammonites), that is, half of Gilead,
Context
1Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Israẹli ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, láti odò Arnoni dé òkè Hermoni, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù: 2Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni.
Ó ṣe àkóso láti Aroeri tí ń bẹ ní etí odò Arnoni, láti ìlú tó wà ní àárín àfonífojì náà dé odò Jabbok, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ammoni. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gileadi. 3Ó sì ṣe àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kinnereti sí ìhà Òkun ti aginjù (ti o túmọ̀ sí Òkun Iyọ̀), sí Beti-Jeṣimoti, àti láti gúúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Pisga. 4Àti agbègbè Ogu ọba Baṣani, ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Refaimu, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.