Joṣua 12:4
Joshua 12:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti agbègbè Ogu ọba Baṣani, ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Refaimu, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei.
Joshua 12:4 in English
Joshua 12:4 · Berean Standard Bible
And Og king of Bashan,* one of the remnant of the Rephaim, who lived in Ashtaroth and Edrei.
Context
2Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni.
Ó ṣe àkóso láti Aroeri tí ń bẹ ní etí odò Arnoni, láti ìlú tó wà ní àárín àfonífojì náà dé odò Jabbok, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ammoni. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gileadi. 3Ó sì ṣe àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kinnereti sí ìhà Òkun ti aginjù (ti o túmọ̀ sí Òkun Iyọ̀), sí Beti-Jeṣimoti, àti láti gúúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Pisga. 4Àti agbègbè Ogu ọba Baṣani, ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Refaimu, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei. 5Ó ṣe àkóso ní orí òkè Hermoni, Saleka, Baṣani títí dé ààlà àwọn ènìyàn Geṣuri àti Maakati, àti ìdajì Gileadi dé ààlà Sihoni ọba Heṣboni. 6Mose ìránṣẹ́ Olúwa àti àwọn ọmọ Israẹli sì borí wọn. Mose ìránṣẹ́ Olúwa sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Reubeni, àwọn ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase kí ó jẹ́ ohun ìní wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.