Native Bible

Joshua 11:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Síbẹ̀ Israẹli kò sun ọ̀kankan nínú àwọn ìlú tó wà lórí òkè kéékèèké, àyàfi Hasori nìkan tí Joṣua sun.

Joshua 11:13 in English

Joshua 11:13 · Berean Standard Bible

Yet Israel did not burn any of the cities built on their mounds, except Hazor, which Joshua burned.

Context

11Wọ́n sì fi idà pa gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀. Wọ́n sì pa wọ́n run pátápátá, wọn kò sì fi ohun alààyè kan sílẹ̀; ó sì fi iná sun Hasori fúnra rẹ̀. 12Joṣua sì kó gbogbo àwọn ìlú ọba àti ọba wọn, ó sì fi idà pa wọ́n. Ó sì run gbogbo wọn, gẹ́gẹ́ bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ. 13Síbẹ̀ Israẹli kò sun ọ̀kankan nínú àwọn ìlú tó wà lórí òkè kéékèèké, àyàfi Hasori nìkan tí Joṣua sun. 14Àwọn ará Israẹli sì kó gbogbo ìkógun àti ohun ọ̀sìn ti ìlú náà fún ara wọn. Wọ́n sì fi idà pa gbogbo ènìyàn títí wọ́n fi run wọ́n pátápátá, kò sí ẹni tí ó wà láààyè. 15Bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní Mose pàṣẹ fún Joṣua, Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò fi ọ̀kankan sílẹ̀ láìṣe nínú gbogbo ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mose.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.