Native Bible

Joshua 11:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní Mose pàṣẹ fún Joṣua, Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò fi ọ̀kankan sílẹ̀ láìṣe nínú gbogbo ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mose.

Joshua 11:15 in English

Joshua 11:15 · Berean Standard Bible

As the LORD had commanded His servant Moses, so Moses commanded Joshua. That is what Joshua did, leaving nothing undone of all that the LORD had commanded Moses.

Context

13Síbẹ̀ Israẹli kò sun ọ̀kankan nínú àwọn ìlú tó wà lórí òkè kéékèèké, àyàfi Hasori nìkan tí Joṣua sun. 14Àwọn ará Israẹli sì kó gbogbo ìkógun àti ohun ọ̀sìn ti ìlú náà fún ara wọn. Wọ́n sì fi idà pa gbogbo ènìyàn títí wọ́n fi run wọ́n pátápátá, kò sí ẹni tí ó wà láààyè. 15Bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní Mose pàṣẹ fún Joṣua, Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò fi ọ̀kankan sílẹ̀ láìṣe nínú gbogbo ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mose. 16Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua gba gbogbo ilẹ̀ náà: ilẹ̀ òkè, gbogbo gúúsù, gbogbo agbègbè Goṣeni, ẹsẹ̀ òkè ti ìwọ̀-oòrùn, aginjù àti àwọn òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Israẹli, 17láti òkè Halaki títí dé òkè Seiri, sí Baali-Gadi ní àfonífojì Lebanoni ní ìsàlẹ̀ òkè Hermoni. Ó sì mú gbogbo ọba wọn, ó sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.