Native Bible

Joshua 11:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

láti òkè Halaki títí dé òkè Seiri, sí Baali-Gadi ní àfonífojì Lebanoni ní ìsàlẹ̀ òkè Hermoni. Ó sì mú gbogbo ọba wọn, ó sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n.

Joshua 11:17 in English

Joshua 11:17 · Berean Standard Bible

from Mount Halak, which rises toward Seir, as far as Baal-gad in the Valley of Lebanon at the foot of Mount Hermon. He captured all their kings and struck them down, putting them to death.

Context

15Bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní Mose pàṣẹ fún Joṣua, Joṣua sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kò fi ọ̀kankan sílẹ̀ láìṣe nínú gbogbo ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mose. 16Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua gba gbogbo ilẹ̀ náà: ilẹ̀ òkè, gbogbo gúúsù, gbogbo agbègbè Goṣeni, ẹsẹ̀ òkè ti ìwọ̀-oòrùn, aginjù àti àwọn òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Israẹli, 17láti òkè Halaki títí dé òkè Seiri, sí Baali-Gadi ní àfonífojì Lebanoni ní ìsàlẹ̀ òkè Hermoni. Ó sì mú gbogbo ọba wọn, ó sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n. 18Joṣua sì bá gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí jagun ní ọjọ́ pípẹ́. 19Kò sí ìlú kan tí ó bá àwọn ará Israẹli ṣe àdéhùn àlàáfíà, àyàfi àwọn ará Hifi tí wọ́n ń gbé ní Gibeoni, gbogbo wọn ló bá a jagun.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.