Jona 2:3
Jonah 2:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí tí ìwọ ti sọ mí sínú ibú, ní àárín Òkun, ìṣàn omi sì yí mi káàkiri; gbogbo bíbì omi àti rírú omi rékọjá lórí mi.
Jonah 2:3 in English
Jonah 2:3 · Berean Standard Bible
For You cast me into the deep, into the heart of the seas, and the current swirled about me; all Your breakers and waves swept over me.
Context
1Nígbà náà ni Jona gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ láti inú ẹja náà wá, 2Ó sì wí pé:
“Nínú ìpọ́njú mi ni mo kígbe sí Olúwa,
òun sì gbọ́ ohùn mi.
Mo kígbe láti inú ipò òkú, mo pè fún ìrànwọ́,
ìwọ sì gbọ́ ohùn mi. 3Nítorí tí ìwọ ti sọ mí sínú ibú,
ní àárín Òkun,
ìṣàn omi sì yí mi káàkiri;
gbogbo bíbì omi àti rírú omi
rékọjá lórí mi. 4Nígbà náà ni mo wí pé,
‘A ta mí nù kúrò níwájú rẹ;
ṣùgbọ́n síbẹ̀ èmi yóò tún
máa wo ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ.’ 5Omi yí mi káàkiri, àní títí dé ọkàn;
ibú yí mi káàkiri,
a fi koríko odò wé mi lórí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.