Native Bible

Joel 3:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa yóò sí ké ramúramù láti Sioni wá, yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerusalẹmu wá; àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì. Ṣùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀, àti agbára àwọn ọmọ Israẹli.

Joel 3:16 in English

Joel 3:16 · Berean Standard Bible

The LORD will roar from Zion and raise His voice from Jerusalem; heaven and earth will tremble. But the LORD will be a refuge for His people, a stronghold for the people of Israel.

Context

14Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní àfonífojì ìpinnu! Nítorí ọjọ́ Olúwa kù si dẹ̀dẹ̀ ní àfonífojì ìdájọ́. 15Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn, àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́. 16Olúwa yóò sí ké ramúramù láti Sioni wá, yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerusalẹmu wá; àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì. Ṣùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀, àti agbára àwọn ọmọ Israẹli. 17“Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ń gbé Sioni òkè mímọ́ mi. Ìgbà náà ni Jerusalẹmu yóò jẹ́ mímọ́; àwọn àjèjì kì yóò sì kó o mọ́. 18“Ní ọjọ́ náà, àwọn òkè ńlá yóò máa kán ọtí wáìnì tuntun sílẹ̀, àwọn òkè kéékèèké yóò máa sàn fún wàrà; gbogbo odò Juda tí ó gbẹ́ yóò máa sàn fún omi. Orísun kan yóò sì ṣàn jáde láti inú ilé Olúwa wá, yóò sì rin omi sí àfonífojì Ṣittimu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.