Joẹli 3:15
Joel 3:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn, àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́.
Joel 3:15 in English
Joel 3:15 · Berean Standard Bible
The sun and moon will grow dark, and the stars will no longer shine.
Context
13Ẹ tẹ dòjé bọ̀ ọ́,
nítorí ìkórè pọ́n.
Ẹ wá, ẹ sọ̀kalẹ̀,
nítorí ìfúntí kún,
nítorí àwọn ọpọ́n kún àkúnwọ́sílẹ̀,
nítorí ìwà búburú wọn pọ̀!” 14Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀
ní àfonífojì ìpinnu!
Nítorí ọjọ́ Olúwa kù si dẹ̀dẹ̀
ní àfonífojì ìdájọ́. 15Oòrùn àti òṣùpá yóò ṣú òkùnkùn,
àti àwọn ìràwọ̀ kí yóò tan ìmọ́lẹ̀ wọn mọ́. 16Olúwa yóò sí ké ramúramù láti Sioni wá,
yóò sì fọ ohùn rẹ̀ jáde láti Jerusalẹmu wá;
àwọn ọ̀run àti ayé yóò sì mì tìtì.
Ṣùgbọ́n Olúwa yóò ṣe ààbò àwọn ènìyàn rẹ̀,
àti agbára àwọn ọmọ Israẹli. 17“Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín,
tí ń gbé Sioni òkè mímọ́ mi.
Ìgbà náà ni Jerusalẹmu yóò jẹ́ mímọ́;
àwọn àjèjì kì yóò sì kó o mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.