Joẹli 1:16
Joel 1:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A kò ha ké oúnjẹ kúrò níwájú ojú wá yìí, ayọ̀ àti inú dídùn kúrò nínú ilé Ọlọ́run wá?
Joel 1:16 in English
Joel 1:16 · Berean Standard Bible
Has not the food been cut off before our very eyes— joy and gladness from the house of our God?
Context
14Ẹ yà àwẹ̀ kan sí mímọ́,
ẹ pe àjọ kan tí o ní ìrònú,
ẹ pe àwọn àgbàgbà,
àti gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà
jọ sí ilé Olúwa Ọlọ́run yín,
kí ẹ sí ké pe Olúwa. 15A! Fún ọjọ́ náà,
nítorí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀,
yóò de bí ìparun láti ọwọ́ Olódùmarè. 16A kò ha ké oúnjẹ kúrò níwájú
ojú wá yìí,
ayọ̀ àti inú dídùn kúrò nínú ilé
Ọlọ́run wá? 17Irúgbìn bàjẹ́ nínú ebè wọn,
a sọ àká di ahoro, a wó àká palẹ̀;
nítorí tí a mú ọkà rọ. 18Àwọn ẹranko tí ń kérora tó!
Àwọn agbo ẹran dààmú,
nítorí tí wọ́n kò ni pápá oko;
nítòótọ́, àwọn agbo àgùntàn jìyà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.