Joẹli 1:18
Joel 1:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ẹranko tí ń kérora tó! Àwọn agbo ẹran dààmú, nítorí tí wọ́n kò ni pápá oko; nítòótọ́, àwọn agbo àgùntàn jìyà.
Joel 1:18 in English
Joel 1:18 · Berean Standard Bible
How the cattle groan! The herds wander in confusion because they have no pasture. Even the flocks of sheep are suffering.
Context
16A kò ha ké oúnjẹ kúrò níwájú
ojú wá yìí,
ayọ̀ àti inú dídùn kúrò nínú ilé
Ọlọ́run wá? 17Irúgbìn bàjẹ́ nínú ebè wọn,
a sọ àká di ahoro, a wó àká palẹ̀;
nítorí tí a mú ọkà rọ. 18Àwọn ẹranko tí ń kérora tó!
Àwọn agbo ẹran dààmú,
nítorí tí wọ́n kò ni pápá oko;
nítòótọ́, àwọn agbo àgùntàn jìyà. 19Olúwa, sí ọ ni èmi o ké pè,
nítorí iná tí run pápá oko tútù aginjù,
ọwọ́ iná sí ti jó gbogbo igi igbó. 20Àwọn ẹranko igbó gbé ojú sókè sí ọ pẹ̀lú,
nítorí tí àwọn ìṣàn omi gbẹ,
iná sí ti jó àwọn pápá oko aginjù run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.