Native Bible

Joel 1:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ yà àwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ kan tí o ní ìrònú, ẹ pe àwọn àgbàgbà, àti gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà jọ sí ilé Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ sí ké pe Olúwa.

Joel 1:14 in English

Joel 1:14 · Berean Standard Bible

Consecrate a fast; proclaim a solemn assembly! Gather the elders and all the residents of the land to the house of the LORD your God, and cry out to the LORD.

Context

12Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù; igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú, àti igi apiili, gbogbo igi igbó ni o rọ. Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn. 13Ẹ di ara yín ni àmùrè, sí pohùnréré ẹkún ẹ̀yin àlùfáà: ẹ pohùnréré ẹkún, ẹ̀yin ìránṣẹ́ pẹpẹ: ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run mi, nítorí tí a dá ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ mímu dúró ní ilé Ọlọ́run yín. 14Ẹ yà àwẹ̀ kan sí mímọ́, ẹ pe àjọ kan tí o ní ìrònú, ẹ pe àwọn àgbàgbà, àti gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà jọ sí ilé Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ sí ké pe Olúwa. 15A! Fún ọjọ́ náà, nítorí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, yóò de bí ìparun láti ọwọ́ Olódùmarè. 16A kò ha ké oúnjẹ kúrò níwájú ojú wá yìí, ayọ̀ àti inú dídùn kúrò nínú ilé Ọlọ́run wá?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.