Native Bible

Job 6:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìbá wúwo jú iyanrìn òkun lọ, nítorí náà ni ọ̀rọ̀ mi ṣe ń tàsé.

Job 6:3 in English

Job 6:3 · Berean Standard Bible

For then it would outweigh the sand of the seas— no wonder my words have been rash.

Context

1Jobu sì dáhùn ó si wí pé, 2“Háà! À bá lè wọ́n ìbìnújẹ́ mi nínú òsùwọ̀n, kí a sì le gbé ọ̀fọ̀ mi lé orí òsùwọ̀n ṣọ̀kan pọ̀! 3Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìbá wúwo jú iyanrìn òkun lọ, nítorí náà ni ọ̀rọ̀ mi ṣe ń tàsé. 4Nítorí pé ọfà Olódùmarè wọ̀ mi nínú, oró èyí tí ọkàn mi mú; ìpayà-ẹ̀rù Ọlọ́run dúró tì mí. 5Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó á máa dún nígbà tí ó bá ní koríko, tàbí ọ̀dá màlúù a máa dún lórí ìjẹ rẹ̀?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.