Jobu 6:4
Job 6:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé ọfà Olódùmarè wọ̀ mi nínú, oró èyí tí ọkàn mi mú; ìpayà-ẹ̀rù Ọlọ́run dúró tì mí.
Job 6:4 in English
Job 6:4 · Berean Standard Bible
For the arrows of the Almighty have pierced me; my spirit drinks in their poison; the terrors of God are arrayed against me.
Context
2“Háà! À bá lè wọ́n ìbìnújẹ́ mi nínú òsùwọ̀n,
kí a sì le gbé ọ̀fọ̀ mi lé orí òsùwọ̀n ṣọ̀kan pọ̀! 3Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìbá wúwo jú iyanrìn òkun lọ,
nítorí náà ni ọ̀rọ̀ mi ṣe ń tàsé. 4Nítorí pé ọfà Olódùmarè wọ̀ mi nínú,
oró èyí tí ọkàn mi mú;
ìpayà-ẹ̀rù Ọlọ́run dúró tì mí. 5Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó á máa dún nígbà tí ó bá ní koríko,
tàbí ọ̀dá màlúù a máa dún lórí ìjẹ rẹ̀? 6A ha lè jẹ ohun tí kò ní adùn ní àìní iyọ̀,
tàbí adùn ha wà nínú funfun ẹyin?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.