Jobu 39:21
Job 39:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú àfonífojì, ó sì yọ̀ nínú agbára rẹ̀; ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun.
Job 39:21 in English
Job 39:21 · Berean Standard Bible
He paws in the valley and rejoices in his strength; he charges into battle.
Context
19“Ìwọ ni ó fi agbára fún ẹṣin bí,
tàbí ṣé ìwọ ni ó fi gọ̀gọ̀ wọ ọrùn rẹ̀ ní aṣọ? 20Ìwọ le mú fò sókè bí ẹlẹ́ǹgà?
Ògo èémí imú rẹ ní ẹ̀rù ńlá. 21Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú àfonífojì, ó sì yọ̀ nínú agbára rẹ̀;
ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun. 22Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kò sì fò ó;
bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà sẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà. 23Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mì pẹkẹpẹkẹ,
àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.