Native Bible

Job 34:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ó sì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn.

Job 34:8 in English

Job 34:8 · Berean Standard Bible

He keeps company with evildoers and walks with wicked men.

Context

6Èmi ha purọ́ sí ẹ̀tọ́ mi bí, bí mo tilẹ̀ jẹ́ aláìjẹ̀bi, ọfà rẹ̀ kò ní àwòtán ọgbẹ́.’ 7Ọkùnrin wo ni ó dàbí Jobu, tí ń mu ẹ̀gàn bí ẹní mú omi? 8Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ó sì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn. 9Nítorí ó sá ti wí pé, ‘Èrè kan kò sí fún ènìyàn, tí yóò fi máa ṣe inú dídùn sí Ọlọ́run.’ 10“Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ fetísílẹ̀ sí mi, ẹ fi etí sí mi ẹ̀yin ènìyàn amòye: Ó di èèwọ̀ fún Ọlọ́run ti ìbá fi hùwà búburú, àti fún Olódùmarè, tí yóò fi ṣe àìṣedéédéé!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.