Jobu 34:10
Job 34:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ fetísílẹ̀ sí mi, ẹ fi etí sí mi ẹ̀yin ènìyàn amòye: Ó di èèwọ̀ fún Ọlọ́run ti ìbá fi hùwà búburú, àti fún Olódùmarè, tí yóò fi ṣe àìṣedéédéé!
Job 34:10 in English
Job 34:10 · Berean Standard Bible
Therefore listen to me, O men of understanding. Far be it from God to do wrong, and from the Almighty to act unjustly.
Context
8Tí ń bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́ tí ó
sì ń bá àwọn ènìyàn búburú rìn. 9Nítorí ó sá ti wí pé, ‘Èrè kan kò sí fún ènìyàn,
tí yóò fi máa ṣe inú dídùn sí Ọlọ́run.’ 10“Ǹjẹ́ nítorí náà, ẹ fetísílẹ̀ sí mi,
ẹ fi etí sí mi ẹ̀yin ènìyàn amòye:
Ó di èèwọ̀ fún Ọlọ́run ti ìbá fi hùwà búburú,
àti fún Olódùmarè, tí yóò fi ṣe àìṣedéédéé! 11Nítorí pé ó ń sán fún ènìyàn fún gẹ́gẹ́ bi ohun tí a bá ṣe,
yóò sì mú olúkúlùkù kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ipa ọ̀nà rẹ̀. 12Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò hùwàkiwà;
bẹ́ẹ̀ ni Olódùmarè kì yóò yí ìdájọ́ po.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.