Native Bible

Job 34:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹni tí ó kórìíra òtítọ́ ha le ṣe olórí bí? Ìwọ ó ha sì dá olóòótọ́ àti ẹni ńlá lẹ́bi?

Job 34:17 in English

Job 34:17 · Berean Standard Bible

Could one who hates justice govern? Will you condemn the just and mighty One,

Context

15gbogbo ènìyàn ni yóò parun pọ̀, ènìyàn a sì tún padà di erùpẹ̀. 16“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, bí ìwọ bá ní òye, gbọ́ èyí; fetísí ohùn ẹnu mi. 17Ẹni tí ó kórìíra òtítọ́ ha le ṣe olórí bí? Ìwọ ó ha sì dá olóòótọ́ àti ẹni ńlá lẹ́bi? 18O ha tọ́ láti wí fún ọba pé, ‘Ènìyàn búburú ní ìwọ,’ tàbí fún àwọn ọmọ-aládé pé, ‘Ìkà ni ẹ̀yin,’ 19mélòó mélòó fún ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn ọmọ-aládé tàbí tí kò kà ọlọ́rọ̀ sí ju tálákà lọ, nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn í ṣe?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.