Native Bible

Job 33:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

láti mú ọkàn rẹ padà kúrò nínú isà òkú, láti fi ìmọ́lẹ̀ alààyè han sí i.

Job 33:30 in English

Job 33:30 · Berean Standard Bible

to bring back his soul from the Pit, that he may be enlightened with the light of life.

Context

28Ọlọ́run ti gba ọkàn mi kúrò nínú lílọ sínú ihò, ẹ̀mí mi yóò wà láti jẹ adùn ìmọ́lẹ̀ ayé.’ 29“Wò ó! Nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run máa ń ṣe fún ènìyàn nígbà méjì àti nígbà mẹ́ta, 30láti mú ọkàn rẹ padà kúrò nínú isà òkú, láti fi ìmọ́lẹ̀ alààyè han sí i. 31“Jobu, kíyèsi i gidigidi, kí o sì fetí sí mi; pa ẹnu rẹ mọ́, èmi ó sì máa sọ ọ́. 32Bí ìwọ bá sì ní ohun wí, dá mi lóhùn; máa sọ, nítorí pé èmi fẹ́ dá ọ láre.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.