Jobu 33:26
Job 33:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun sì ṣe ojúrere rẹ̀, o sì rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀, òhun o san òdodo rẹ̀ padà fún ènìyàn.
Job 33:26 in English
Job 33:26 · Berean Standard Bible
He prays to God and finds favor; he sees God’s face and shouts for joy, and God restores His righteousness to that man.
Context
24nígbà náà ni ó ṣe oore-ọ̀fẹ́ fún un ó sì wí pé,
gbà á kúrò nínú lílọ sínú isà òkú;
èmi ti rà á padà. 25Ara rẹ̀ yóò sì di ọ̀tun bí i ti ọmọ kékeré,
yóò sì tún padà sí ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀; 26Ó gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun sì ṣe ojúrere rẹ̀,
o sì rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀,
òhun o san òdodo rẹ̀ padà fún ènìyàn. 27Ó wá sọ́dọ̀ ènìyàn ó sì wí pé,
‘Èmi ṣẹ̀, kò sì ṣí èyí tí o tọ́, mo sì ti yí èyí tí ó tọ́ po,
a kò sì san ẹ̀san rẹ̀ fún mi; 28Ọlọ́run ti gba ọkàn mi kúrò nínú lílọ sínú ihò,
ẹ̀mí mi yóò wà láti jẹ adùn ìmọ́lẹ̀ ayé.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.