Native Bible

Job 33:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ara rẹ̀ yóò sì di ọ̀tun bí i ti ọmọ kékeré, yóò sì tún padà sí ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀;

Job 33:25 in English

Job 33:25 · Berean Standard Bible

then his flesh is refreshed like a child’s; he returns to the days of his youth.

Context

23Bí angẹli kan ba wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ẹni tí ń ṣe alágbàwí, ọ̀kan nínú ẹgbẹ̀rún (1,000) láti fi ọ̀nà pípé hàn ni, 24nígbà náà ni ó ṣe oore-ọ̀fẹ́ fún un ó sì wí pé, gbà á kúrò nínú lílọ sínú isà òkú; èmi ti rà á padà. 25Ara rẹ̀ yóò sì di ọ̀tun bí i ti ọmọ kékeré, yóò sì tún padà sí ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀; 26Ó gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun sì ṣe ojúrere rẹ̀, o sì rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀, òhun o san òdodo rẹ̀ padà fún ènìyàn. 27Ó wá sọ́dọ̀ ènìyàn ó sì wí pé, ‘Èmi ṣẹ̀, kò sì ṣí èyí tí o tọ́, mo sì ti yí èyí tí ó tọ́ po, a kò sì san ẹ̀san rẹ̀ fún mi;

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.