Jobu 32:7
Job 32:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi wí pé ọjọ́ orí ni ìbá sọ̀rọ̀, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìbá kọ́ ni ní ọgbọ́n.
Job 32:7 in English
Job 32:7 · Berean Standard Bible
I thought that age should speak, and many years should teach wisdom.
Context
5Nígbà tí Elihu rí i pé ìdáhùn ọ̀rọ̀ kò sí ní ẹnu àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí nígbà náà ni ó bínú. 6Elihu, ọmọ Barakeli, ará Busi, dáhùn ó sì wí pé,
“Ọmọdé ni èmi,
àgbà sì ní ẹ̀yin;
ǹjẹ́ nítorí náà ní mo dúró,
mo sì ń bẹ̀rù láti fi ìmọ̀ mi hàn yin. 7Èmi wí pé ọjọ́ orí ni ìbá sọ̀rọ̀,
àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìbá kọ́ ni ní ọgbọ́n. 8Ṣùgbọ́n ẹ̀mí kan ní ó wà nínú ènìyàn
àti ìmísí Olódùmarè ní ì sì máa fún wọn ní òye. 9Ènìyàn ńlá ńlá kì í ṣe ọlọ́gbọ́n,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà ní òye ẹ̀tọ́ kò yé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.