Jobu 32:10
Job 32:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé, ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi; èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn.
Job 32:10 in English
Job 32:10 · Berean Standard Bible
Therefore I say, ‘Listen to me; I too will declare what I know.’
Context
8Ṣùgbọ́n ẹ̀mí kan ní ó wà nínú ènìyàn
àti ìmísí Olódùmarè ní ì sì máa fún wọn ní òye. 9Ènìyàn ńlá ńlá kì í ṣe ọlọ́gbọ́n,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà ní òye ẹ̀tọ́ kò yé. 10“Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé, ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi;
èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn. 11Kíyèsi i, èmí ti dúró de ọ̀rọ̀ yín;
èmi fetísí àròyé yín,
nígbà tí ẹ̀yin ń wá ọ̀rọ̀ ti ẹ̀yin yóò sọ; 12àní, mo fiyèsí yín tinútinú.
Sì kíyèsi i, kò sí ẹnìkan nínú yín tí ó le já Jobu ní irọ́;
tàbí tí ó lè dá a lóhùn àríyànjiyàn rẹ̀!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.