Jobu 32:12
Job 32:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àní, mo fiyèsí yín tinútinú. Sì kíyèsi i, kò sí ẹnìkan nínú yín tí ó le já Jobu ní irọ́; tàbí tí ó lè dá a lóhùn àríyànjiyàn rẹ̀!
Job 32:12 in English
Job 32:12 · Berean Standard Bible
I paid you full attention. But no one proved Job wrong; not one of you rebutted his arguments.
Context
10“Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé, ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi;
èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn. 11Kíyèsi i, èmí ti dúró de ọ̀rọ̀ yín;
èmi fetísí àròyé yín,
nígbà tí ẹ̀yin ń wá ọ̀rọ̀ ti ẹ̀yin yóò sọ; 12àní, mo fiyèsí yín tinútinú.
Sì kíyèsi i, kò sí ẹnìkan nínú yín tí ó le já Jobu ní irọ́;
tàbí tí ó lè dá a lóhùn àríyànjiyàn rẹ̀! 13Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe wí pé, ‘Àwa wá ọgbọ́n ní àwárí;
Ọlọ́run ni ó lè bì í ṣubú kì í ṣe ènìyàn.’ 14Bí òun kò ti sọ̀rọ̀ sí mi,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ọ̀rọ̀ yín dá a lóhùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.