Native Bible

Job 28:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.

Job 28:13 in English

Job 28:13 · Berean Standard Bible

No man can know its value, nor is it found in the land of the living.

Context

11Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún àkúnya, ó sì mú ohun tí ó pamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀. 12Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí, níbo sì ni òye ń gbe? 13Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè. 14Ọ̀gbun wí pé, “Kò sí nínú mi”; omi òkun sì wí pé, “Kò si nínú mi.” 15A kò le è fi wúrà rà á, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òsùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.