Jobu 28:10
Job 28:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta, ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo.
Job 28:10 in English
Job 28:10 · Berean Standard Bible
He hews out channels in the rocks, and his eyes spot every treasure.
Context
8Àwọn ẹranko agbéraga kò rìn ibẹ̀ rí,
bẹ́ẹ̀ ni kìnnìún tí ń ké ramúramù kò kọjá níbẹ̀ rí. 9Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta,
ó yí òkè ńlá po láti ìdí rẹ̀ wá. 10Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta,
ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo. 11Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún àkúnya,
ó sì mú ohun tí ó pamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀. 12Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí,
níbo sì ni òye ń gbe?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.