Jobu 27:16
Job 27:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ó tilẹ̀ kó fàdákà jọ bí erùpẹ̀, tí ó sì dá aṣọ jọ bí amọ̀;
Job 27:16 in English
Job 27:16 · Berean Standard Bible
Though he heaps up silver like dust and piles up a wardrobe like clay,
Context
14Bí àwọn ọmọ rẹ bá di púpọ̀, fún idà ni;
àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ kì yóò yó fún oúnjẹ. 15Àwọn tí ó kù nínú tirẹ̀ ni a ó sìnkú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn:
àwọn opó rẹ̀ kì yóò sì sọkún fún wọn. 16Bí ó tilẹ̀ kó fàdákà jọ bí erùpẹ̀,
tí ó sì dá aṣọ jọ bí amọ̀; 17àwọn ohun tí ó tò jọ àwọn olóòtítọ́ ni yóò lò ó;
àwọn aláìṣẹ̀ ni yóò sì pín fàdákà rẹ̀. 18Òun kọ́ ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kòkòrò aṣọ,
àti bí ahéré tí olùṣọ́ kọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.