Jobu 27:15
Job 27:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn tí ó kù nínú tirẹ̀ ni a ó sìnkú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn: àwọn opó rẹ̀ kì yóò sì sọkún fún wọn.
Job 27:15 in English
Job 27:15 · Berean Standard Bible
His survivors will be buried by the plague, and their widows will not weep for them.
Context
13“Ẹ̀yin ni ìpín ènìyàn búburú lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
àti ogún àwọn aninilára, tí wọ́n ó gbà lọ́wọ́ Olódùmarè. 14Bí àwọn ọmọ rẹ bá di púpọ̀, fún idà ni;
àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ kì yóò yó fún oúnjẹ. 15Àwọn tí ó kù nínú tirẹ̀ ni a ó sìnkú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn:
àwọn opó rẹ̀ kì yóò sì sọkún fún wọn. 16Bí ó tilẹ̀ kó fàdákà jọ bí erùpẹ̀,
tí ó sì dá aṣọ jọ bí amọ̀; 17àwọn ohun tí ó tò jọ àwọn olóòtítọ́ ni yóò lò ó;
àwọn aláìṣẹ̀ ni yóò sì pín fàdákà rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.