Native Bible

Job 18:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àìlera rẹ̀ yóò di púpọ̀ fún ebi, ìparun yóò dìde dúró sí i nígbà tí ó bá ṣubú.

Job 18:12 in English

Job 18:12 · Berean Standard Bible

His strength is depleted, and calamity is ready at his side.

Context

10A dẹkùn sílẹ̀ fún un lórí ilẹ̀, a sì wà ọ̀fìn fún un lójú ọ̀nà. 11Ẹ̀rù ńlá yóò bà á ní ìhà gbogbo, yóò sì lé e dé ẹsẹ̀ rẹ̀. 12Àìlera rẹ̀ yóò di púpọ̀ fún ebi, ìparun yóò dìde dúró sí i nígbà tí ó bá ṣubú. 13Yóò jẹ ẹ̀yà ara rẹ̀; ikú àkọ́bí ni yóò jẹ agbára rẹ̀ run. 14A ó fà á tu kúrò nínú àgọ́ tí ó gbẹ́kẹ̀lé, a ó sì mú un tọ ọba ẹ̀rù ńlá nì lọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.