Native Bible

Job 18:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A ó fà á tu kúrò nínú àgọ́ tí ó gbẹ́kẹ̀lé, a ó sì mú un tọ ọba ẹ̀rù ńlá nì lọ.

Job 18:14 in English

Job 18:14 · Berean Standard Bible

He is torn from the shelter of his tent and is marched off to the king of terrors.

Context

12Àìlera rẹ̀ yóò di púpọ̀ fún ebi, ìparun yóò dìde dúró sí i nígbà tí ó bá ṣubú. 13Yóò jẹ ẹ̀yà ara rẹ̀; ikú àkọ́bí ni yóò jẹ agbára rẹ̀ run. 14A ó fà á tu kúrò nínú àgọ́ tí ó gbẹ́kẹ̀lé, a ó sì mú un tọ ọba ẹ̀rù ńlá nì lọ. 15Yóò sì máa jókòó nínú àgọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe tirẹ̀; sulfuru ti o jóná ni a ó fún káàkiri ibùgbé rẹ̀. 16Gbòǹgbò rẹ̀ yóò gbẹ níṣàlẹ̀, a ó sì ké ẹ̀ka rẹ̀ kúrò lókè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.