Native Bible

Job 18:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀rù ńlá yóò bà á ní ìhà gbogbo, yóò sì lé e dé ẹsẹ̀ rẹ̀.

Job 18:11 in English

Job 18:11 · Berean Standard Bible

Terrors frighten him on every side and harass his every step.

Context

9Tàkúté ni yóò mú un ní gìgísẹ̀, àwọn àwọ̀n tí a dẹ yóò sì ṣẹ́gun rẹ̀. 10A dẹkùn sílẹ̀ fún un lórí ilẹ̀, a sì wà ọ̀fìn fún un lójú ọ̀nà. 11Ẹ̀rù ńlá yóò bà á ní ìhà gbogbo, yóò sì lé e dé ẹsẹ̀ rẹ̀. 12Àìlera rẹ̀ yóò di púpọ̀ fún ebi, ìparun yóò dìde dúró sí i nígbà tí ó bá ṣubú. 13Yóò jẹ ẹ̀yà ara rẹ̀; ikú àkọ́bí ni yóò jẹ agbára rẹ̀ run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.