Jobu 16:9
Job 16:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọlọ́run fi i ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ó sì gbóguntì mí; ó pa eyín rẹ̀ keke sí mi, ọ̀tá mi sì gbójú rẹ̀ sí mi.
Job 16:9 in English
Job 16:9 · Berean Standard Bible
His anger has torn me and opposed me; He gnashes His teeth at me. My adversary pierces me with His eyes.
Context
7Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó dá mi lágara;
ìwọ Ọlọ́run mú gbogbo ẹgbẹ́ mi takété. 8Ìwọ fi ìhunjọ kùn mí lára, èyí tí o jẹ́rìí tì mí;
àti rírù tí ó hàn lára mi, ó jẹ́rìí tì mí ní ojú. 9Ọlọ́run fi i ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ó sì gbóguntì mí;
ó pa eyín rẹ̀ keke sí mi,
ọ̀tá mi sì gbójú rẹ̀ sí mi. 10Wọ́n ti fi ẹnu wọn yẹ̀yẹ́ mi;
Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbá ẹ̀gàn;
wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi. 11Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹni búburú,
ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.