Jobu 16:13
Job 16:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mi káàkiri. Ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò si dá sí, ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀.
Job 16:13 in English
Job 16:13 · Berean Standard Bible
His archers surround me. He pierces my kidneys without mercy and spills my gall on the ground.
Context
11Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹni búburú,
ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà. 12Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já;
ó sì dì mí ni ọrùn mú, ó sì gbọ̀n mí túútúú,
ó sì gbé mi kalẹ̀ láti ṣe àmì ìtafàsí rẹ̀; 13àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mi káàkiri.
Ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò si dá sí,
ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀. 14Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́;
ó súré kọlù mi bí jagunjagun. 15“Mo rán aṣọ ọ̀fọ̀ bò ara mi,
mo sì rẹ̀ ìwo mi sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.