Native Bible

Job 16:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já; ó sì dì mí ni ọrùn mú, ó sì gbọ̀n mí túútúú, ó sì gbé mi kalẹ̀ láti ṣe àmì ìtafàsí rẹ̀;

Job 16:12 in English

Job 16:12 · Berean Standard Bible

I was at ease, but He shattered me; He seized me by the neck and crushed me. He has set me up as His target;

Context

10Wọ́n ti fi ẹnu wọn yẹ̀yẹ́ mi; Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbá ẹ̀gàn; wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi. 11Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹni búburú, ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà. 12Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já; ó sì dì mí ni ọrùn mú, ó sì gbọ̀n mí túútúú, ó sì gbé mi kalẹ̀ láti ṣe àmì ìtafàsí rẹ̀; 13àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mi káàkiri. Ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò si dá sí, ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀. 14Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́; ó súré kọlù mi bí jagunjagun.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.