Jobu 12:22
Job 12:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó hú ìdí ohun ìjìnlẹ̀ jáde láti inú òkùnkùn wá ó sì mú òjìji ikú wá sínú ìmọ́lẹ̀.
Job 12:22 in English
Job 12:22 · Berean Standard Bible
He reveals the deep things of darkness and brings deep shadows into light.
Context
20Ó mú ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni ìgbẹ́kẹ̀lé kúrò
ó sì ra àwọn àgbàgbà ní iyè. 21Ó bu ẹ̀gàn lu àwọn ọmọ ọlọ́lá
ó sì tú àmùrè àwọn alágbára. 22Ó hú ìdí ohun ìjìnlẹ̀ jáde láti inú òkùnkùn wá
ó sì mú òjìji ikú wá sínú ìmọ́lẹ̀. 23Òun a mú orílẹ̀-èdè bí sí i, a sì run wọ́n;
òun a sọ orílẹ̀-èdè di ńlá, a sì tún ṣẹ̀ wọn kù. 24Òun a gba òye àwọn olórí àwọn ènìyàn aráyé,
a sì máa mú wọn rin kiri nínú ijù níbi tí ọ̀nà kò sí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.