Native Bible

Job 11:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ; ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti sàn kọjá lọ.

Job 11:16 in English

Job 11:16 · Berean Standard Bible

For you will forget your misery, recalling it only as waters gone by.

Context

14bí ìwọ bá gbé ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ jù sọnù tí ìwọ kò sì jẹ́ kí aburú gbé nínú àgọ́ rẹ, 15nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láìní àbàwọ́n, àní ìwọ yóò dúró ṣinṣin, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù. 16Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ; ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti sàn kọjá lọ. 17Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ, bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísinsin yìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀. 18Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà; àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.