Jobu 11:18
Job 11:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà; àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà.
Job 11:18 in English
Job 11:18 · Berean Standard Bible
You will be secure, because there is hope, and you will look around and lie down in safety.
Context
16Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ;
ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti sàn kọjá lọ. 17Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ,
bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísinsin yìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀. 18Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà;
àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà. 19Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́,
àní ènìyàn yóò máa wá ojúrere rẹ. 20Ṣùgbọ́n ojú ìkà ènìyàn yóò mófo;
gbogbo ọ̀nà àbáyọ ni yóò nù wọ́n,
ìrètí wọn a sì dàbí ẹni tí ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.